A ki rọ’ ba fin la lẹ de Ọyo
O ya ẹ jẹ a lo ree ki Alaafin
Ọmọ a jowu yọ kọ lẹnu
A bi Ila tọ-tọ lẹhin
Pan-du-ku bi soo ro
Ibi ti wọn ti ni ki Olowo gbowo
Ki Iwọfa sọ tọ wọ rẹ nu,
Ṣe ko le ba di’ ja, ko le ba di apọn
Ki Ọba Alade le ri n jẹ,
Ọyọ mọ l’ afin Ojo pa Ṣẹkẹrẹ, ọmọ Atiba
Babalawo lo d’ fa, pe ibiti ilẹ gbe yọ ni aye wọn,
Ọyọ ode oni,ni Agọ-Oja, Ọba lo tun tẹ, laye Atiba Ọba,
Adebinpe O Sakẹkẹ, Adebinpe, eji ọgbọrọ, Alade lẹyẹ Akande,
Ọba, aji bo ‘yinbo se le ri,
Ọba taa ri, taa ka po la po, taa kọ fa, lọ fa,
Taa ka pata,lo ri Apata, Bẹmbẹ n ro, imulẹ lẹhin agbara,
Ọdọfin ijaye,o jẹ du ro de la kanlu, ọmọ a ja ni lẹ ran gan-gan,
Eji ọgbọrọ,Alaafin Atiba, Ọba lo ko wo jẹ, Ko to do ri Ọba to wa lo ye,
A ji se bi Ọyọlaa ri, Ọyọ O jẹ se bi baba eni kan-kan
Pin ni si lọ ‘mọ Erin t’ n fọ la ya ‘gi,
Ọyọ lo ni ka rin, ka san pa, ka gbẹsẹ, ko yẹ yan,
Oko ala kẹ, ọmọa fo ko ra lu, t’ wọn o ba mọ Erin,
Se wọn o gbọ‘hun Erin ni,
A ji sọ la, ọmọa jo wu yọ kọ lẹ nu.